1. OLUWA, ‘gbat’ a ngbadura
Fun gbogbo enia,
Gb’adura wa fun ile wa,
Ile t’ a fe julo.
2. Iboji awon baba wa,
‘Busun awon ara,
Bawo l’ awa iba se fe
Ile miran bi re?
3. So ile wa lowo ota,
Si bukun ala wa;
K’ O si fi akoko opo
De oko wa l’ ade.
4. F’ ife mimo si otito
So gbogbo wa d’ okan;
K’ oke ati petele wa
Ko orin omnira.
5. A f’ ilu wa le O lowo,
Oluwa gbogb’ aiye;
Ma se ibi isadi re,
At’ ore re lailai.
(Visited 329 times, 1 visits today)