YBH 465

AFRIK’ ‘le wara at’ oyin

1. AFRIK’ ‘le wara at’ oyin,
Ni orile aiye now si,
T’ Olorun fun ania dudu,
Fun ini re titi lailai.

2. Ote owo-eru ‘gbani,
Ko f’ okan baba wa bale,
A ko won lo lairotele,
Nwon s’ eru, oju sip on won.

3. Ose at’ ekun gb’ ile kan,
Gb’ oko, aya, baba, omo,
Fi tulasi, ‘daro, pinya,
At’ edun t’ enu ko le so.

4. Sugbon b’ Olorun Olore
Ti ranti Isreal nigbani,
O s’ona igbala fun won,
Nwon d’ omnira, omo Kristi.

5. Sibe opo gbagbe ‘le won,
Oluwa a mbe, se ‘ranwo,
Mu won pada si ile won;
Ka si le tubo ma yin O.

6. Eko, ‘laju ‘gbagbo pipe,
Irepo at’ ife toto,
Rojo won lat’ odo Re wa,
S’ ori gbogbo ‘le Afrika.

7. Oluwa Olodumare,
Je k’ ile wa wulo fun wa,
Gbati ‘se wa l’aiye ba pin,
Gba wa s’ orun alafia.

(Visited 247 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you