YBH 476

AYIN O, Oluranwo wa

1. AYIN O, Oluranwo wa,
T’ife Re wa bakanna lai,
Owo ike en’t’ o bere,
Ti o si pari odun wa.

2. Larin egbegberun ‘danwo,
A duro nipa ‘toju Re;
Nigbat’a si bojuw’ ehin,
A r’ opo ohun fun iyin.

3. De ‘hin li apa Re sin wa,
De ‘hin l’ a rohin anu Re;
‘Gbati a nrin l’asale, yi,
Anu bere orin titun.

4. Gb’ okan wa gunle Jordani,
Nwon o tun gbe opo kan ro,
Gba won ba si d’agbala Re,
Nwon o gb’ am’ ife ti ki ku.

(Visited 415 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you