1. OJO ati akoko nlo,
Nwon nsun wa s’ eti ‘boji;
Awa fere dubule na,
Ninu iho ‘busun wa.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
2. Jesu, ‘Wo Olurapada,
Ji okan t’ o ku s’ ese:
Ji gbogbo okan ti ntogbe,
Lati yan ipa iye.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
3. Bi akoko ti nsunmole,
Jek’ a ro ibit’ a nlo;
Bi lati r’ ayo ailopin,
Tabi egbe ailopin.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
3. Aiye wan lo!
Iku de tan.
Jesu, so wa
Tit’ O fi de.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
5. Aiye wa nkoja b’ ojiji,
O si nfo lo bi kuku;
Fun gbogbo odun t’ o koja,
Dariji wa, mu wag bon.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
6. Ko wa lati ka ojo wa,
Lati ba ese wa je;
K’ a ma s’ are, k’ a ma togbe,
Tit’ a o fi ri ‘simi.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
7. Gbogbo wa fere duro na,
Niwaju ite ‘dajo;
Jesu, ‘Wo t’ O segun iku,
Fi wa s’ apa otun Re.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.
8. Aiye wa nlo
Iku de tan.
Olugbala!
Jo pa wa mo.
Refrain
K’ a ba O gbe,
K’ a ba O ku,
K’ a ba O joba titi lailai.