YBH 479

BABA, je nya odun yi

1. BABA, je nya odun yi
Si mimo fun O,
N’ipokipo ti o wu
Ti O fe ki nwa:
Bi ‘banuje on ‘rora
Nko gbodo komnu;
Eyi sa l’ adura mi.
“Ogo f’ oko Re.”

2. Om’ owo ha le pase
‘Biti on y’o gbe?
Baba ‘fe ha le du ni
L’ ebun rere bi?
‘Jojumo n’ Iwo nfun wa
Ju bi o ti to,
O ko du wa l’ ohun kan
T’ y’ o yin O logo.

3. Ninu anu, b’ Iwo ba
Fun mi li ayo,
B’ Alafia on ‘rora
Ba m’ oju mi dan;
Gba okan mi ba nkorin
Je k’ o ma yin O,
Ohun t’ ola ba mu wa
“Ogo f’ oko Re.”

4. B’ O mu ‘ponju wa ba mi,
T’ na mi sokun,
T’ ere mi di adanu,
Ti ile mi kan;
Je ki nranti bi Jesu
Ti d’ Eni ogo,
T’ O ngbadura n’nu ponju,
“Ogo f’ oko Re.”

(Visited 407 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you