1. ODUN miran ti koja,
Wawa l’ akoko na lo,
Ninu eyit’ a wa yi,
Yio se arimo opo;
Anu l’ O fid a wa si,
A ha lo anu na bi?
K’ a bi ‘ra wa b’ a se tan,
B’ a o pew a l’ odun yi?
2. Aiye bi ibi’ija,
Egbegberun l’ o nsubu,
Ofa iku t’ o s info,
A le ran s’ emi b’ iwo;
Nigb’ a nwasu, t’ a si ngbo,
Oluwa je k’ a saro
P’ aiyeraiye sunmole,
A nduro l’ eti bebe.
3. B’ a gba wa lowo ese
Nipa ore-ofe Re,
Nje “ma bo” n’ ipe y’o je,
K’ a le lo, k’ a r’ oju Re:
F’ enia Re l’ aiye yi
K’ anu wa l’ odun titun;
Odun t’ o l’ ayo ju ‘yi,
L’ eyi t’ o mu won de ‘le.
(Visited 2,993 times, 1 visits today)