1. ALAKOSO ti orun,
Alanu at’ Ologbon;
Igba mi mbe l’ owo Re,
Opin gbogbo l’ ase Re.
2. Ase Re l’ o da aiye
Ati ibi mi pelu,
Obi, ile, on igba
Nipa Re ni gbogbo won.
3. Igb’ aisan on ilera,
Igba ise on oro,
Igba danwo, ibinu,
Igba ‘segun, iranwo.
4. Igba iridi Esu,
Igba ‘to fe Jesu wo,
Nwon o wa, nwon o si lo,
B’ Ore wa orun ti ife.
5. Iwo Olore-ofe,
‘Wo ni mo f’ emi Re,
Emi jewo ife Re,
Emi teriba fun O.
(Visited 622 times, 1 visits today)