YBH 482

OLUWA alafia wa

1. OLUWA alafia wa
L’ O pase t’ odun yipo;
Awa omo Re wa dupe
F’ odun titun t’ a bere.
Yin Oluwa!
Oba nla t’ O da wa si.

2. A dupe fun ipamo wa
Ni odun ti o koja;
A mbebe iranlowo Re
Fun gbogbo wa l’ odun yi.
Je k’ Ijo wa
Ma dagba ninu Kristi.

3. K’ agba k’ o mura lati sin
L’ okan kan ni odun yi;
K’ awon omode k’ o mura
Lati s’ aferi Jesu.
K’ alafia
K’ o se ade odun yi.

4. K’ Emi Mimo lat’ oke wa
Ba le wa ni odun yi,
Ki Alufa at’ Oluko,
Pelu gbogbo Ijo wa
Mura giri
Lati josin f’ Oluwa.

(Visited 1,753 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you