1. GBAT’ oju mi ba se peki
‘Mole to se n’ ila orun,
Orun ododo masai ran
Ase anu re s’ ori mi,
K’o le iji ebi kuro
K’o so okun mi d’ imole.
2. Gba m’ ba ebo owuro
Wa siwaju Oba orun,
Ti mo nsofo itiju mi,
Ti mo mbe l’ oruko Jesu;
Olugbala fie je Re
We mi, si s’ Alagbawimi.
3. ‘Gbati ise ojo pari,
Ti ara are fe ‘simi,
F’ idariji anu bukun,
Si so mi nigba m’ba simi;
B’ orun ojo keji tin ran
Ma sin mi lo lona orun.
4. Gbat’ orun aiye mi ba wo,
T’ ija at’ ise mi d’ opin,
Jesu tan ase orun Re
S’ ori akete iku mi,
K’ O ji mi lat’ okun iku,
Lati ri o kin le yin O.
(Visited 516 times, 1 visits today)