YBH 492

JESU awa nwo O fun

1. JESU awa nwo O fun
‘Wosan alailera yi
‘Wo lo ti se anu nla,
F’ abiirun let’ adagun.

2. Ko s’ onisegun bi Re;
Ti w’ ara at’ okan san,
‘Wo lo ji omobirin
Jairu dide nin’ oku.

3. Lasaru ti s’ aisan ri,
O ku, a sin I n’boji,
Sugbon ‘wo ‘nisegun nla,
J’oku ‘jo kerin dide.

4. Jesu jo dari jin wa,
Ba wa wo alaisan yi,
K’ o le dide f’ ogo Re,
Ki a le f’ ope fun O.

5. Wo ko w’ aisan kan ti ri,
Ninu igbe aiye Re,
O ti wi nin’ anu Re,
Pe ‘leri re ko ni ye.

(Visited 177 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you