YBH 493

JESU ‘ wo Onisegun nla

1. JESU ‘ wo Onisegun nla,
T’ olokunrun nf’ ailera mo,
Nigba aisan at’ irora,
O se dida ara fun won.

2. Afoju, aro, alaisan,
Nwon ko sai ri ‘toju re gba,
Torina a wa sodo Re,
A ntoro anu Re nikan.

3. Irora ti ‘wo la koja,
Jesu ‘Wo le se ‘wosan re,
Awon t’o w’ onisegun nla,
Jo masai se iwosan won.

4. Oluwa je ki irora,
M’ alaisan tubo sunmo O,
Ki owo egba Re kokan,
Fa asako sunm’ odo Re.

5. Se ‘wosan okan to gbogbe,
Si gba okan ese wa la,
F’opo ilera Re fun wa,
Ka le ma yin O titilai.

(Visited 272 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you