1. MO gbeke mi le O,
Lori ibusun mi,
Gba mi lowo irora mi,
Ki O si wo mi san.
2. Ko s’ elomiran mo,
Ti mo tun gbekele,
O san fun ‘ya aya Pita,
Ninu ailera re.
3. Obinrin igbani,
Pelu isun eje,
Nipa iseti aso Re,
O ri mularada.
4. Wo mi san Oluwa,
Ninu ailera mi,
Emi ko gbodo ber’ aisan,
Gba mo gbekele O.
(Visited 495 times, 1 visits today)