1. ISE re Oluwa,
Awamaridi ni,
Ohun gbogbo ni mu ‘re wa,
F’ eni to se ‘fe Re.
2. O ri ailera mi,
Aisan at’ aigbadun
Irora mi losan loru,
Orun ko si l’ oju.
3. Wo wahala mi yi,
‘Wo Onisegun nla,
So fun mi bi t’ Hesikaya
“Mo gbo adura re.”
4. W’ awon to nsike mi,
Ati onisegun,
Wi fun mi bi t’ Hesikaya,
“Mo ti r’ omije re.”
5. Ma wo ailera mi,
Dari ese jin mi,
Wo mi san bi t’ Hesikaya,
Si bukun ojo mi.
6. Mu mi wulo fun O,
Lehin ilera mi,
B’ ise mi l’ aiye si d’ opin,
Mu mi wo ‘nu ogo.
(Visited 285 times, 1 visits today)