1. B’ ODO ti nyara san lo,
Li ona gboro re,
Ti omi re nja titi,
T’ o nsare lo s’ okun,
Beni aiye wan san lo,
Ati ojo anu,
Enia si nsare lo si
‘Bit’ ipe anu pin.
2. B’ awon osupa ti now,
Ti orun nsare lo,
B’ irahun iji ti mu
Ojo otutu de,
Be ge l’ oru nde si wa,
Okunkun iboji;
Iku wa n’ iwaju wa;
A gb’ emi t’ a fun ni.
3. Wi, okan re ha ti to
Isura re s’ oke?
Gbogbo ife re ha ni
Lati yin Olorun!
Sora ki odo iku
Ma y’ igbi re bo o,
Si ma sokun titi lai
Fun ‘parun okan re.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.