1. KO mi ni iwon ojo mi,
Iwo Eleda mi;
Mo fe w’ ona toro aiye,
Ki nmo ailera mi.
2. Ese kan pere ni ti wa,
Iseju kan l’ a ni,
Ohun asan ni enia je,
Ninu gbogb’ ogo re.
3. Kini mba fe, ti mba reti
Low’ eru on ile?
Nwon so ireti wa d’ asan,
At’ igbekele wa.
4. Mo da ‘reti ara l’ ekun,
Mo pe ‘fe mi pada,
Mo f’ ohun ti mo fe sile,
Mo d’ Olorun mi mu.
(Visited 251 times, 1 visits today)