YBH 498

OLORUN lat’ irandiran

1. OLORUN lat’ irandiran,
‘Wo n’ isimi at’ abo wa,
K’ a to da orun at’ aiye,
Giga ni ife Re l’ oke.

2. O ti njoba k’ igba to wa,
Tabi k’ a to da enia;
Ijoba Re yio wa lailai,
‘Gbat’ igba at’ aiye ba pin.

3. Iku, bi oko, ngba wa lo,
Aiye wa bi tan lasan,
O dab’ itanna owuro,
Ti a ke lu ‘le, t’ o sir o.

4. Jek’ a mo ailera eda,
K’ O sun ojo wa siwaju,
Tit’ ao fi mura de iku,
Nipa ‘ enumo or’-ofe.

(Visited 232 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you