1. ILE ‘simi, mo nreti re,
‘Gbawo n’ igba yio de,
Ti ngo bo ‘hamora sile,
Ti ngo wa pelu Krist”?
A’o sise Jesu,
A o sise Jesu,
Titi ‘Wo y’o fi de
Lati mu wa lo ‘le.
2. Ko s’ ayo ti mo mo l’ aiye,
Ko s’ ibi isimi,
Aginju egbe l’ aiye yi,
Aiye ki se ‘le mi,
3. Mo to Jesu wa fun ‘simi,
O ni kin ye kiri,
Ki nsa s’ aiya On fun ‘ranwo,
On yio to mi de ‘le,
4. Arinka yi tile su mi,
N’nu ese at’ osi,
Mo fe f’ ile ailowo le,
Ki mba Krist’ gbe l’ oke,
(Visited 286 times, 1 visits today)