1. AKOKO ati lo mi ya,
Mo gb’ ohun to npe mi lo ‘le,
Olorun jek’ iyonu pin,
Jek’ iranse Re ku l’ ayo.
2. Mo ti sare ije mi tan,
Ija pari, mo ti gb’ ere,
Eleri mi si wa, l’ oke,
Iwe ise mi wa l’ orun.
3. Nko gbekele ododo mi,
Mo wole ni iwaju Re,
Mo si nw’ anu nib’ ite Re,
Nipa eje Jesu nikan.
4. Oluwa, mo de l’ ase Re,
Mo f’ emi mi le O lowo,
Na apa Re t’ o l’ agbara,
Fi bo mi n’nu iji ‘kehin.
(Visited 238 times, 1 visits today)