1. NIGBAT’ imole owuro
Ba nti ila orun tan wa,
A! Orun ododo mimo
Ma sai fi anu ran si mi!
Tu isudede ebi ka
S’ okunkun mi d’ imole nla.
2. Gbat mba m’ebo oro wa
‘Waju Olorun t’ O l’ogo,
Olugbala, ti mba nkanu
Nitori ese ti mo da,
Jesu! fi eje Re we mi,
Ma sai se Alagbawi mi.
3. ‘Gba gbogbo ise ojo pin,
Ti ara si nfe lo simi,
F’ anu t’o kun fun ‘dariji,
Dabobo mi, Oluwa mi;
Bi orun si ti ‘ma goke,
Beni k’o gb’ ero mi s’oke.
4. ‘Gbat’ orun aiye mi ba wo,
Ti ko si si wahala mo,
Je k’imole Tire, Jesu!
Tan ‘boji ti mo sun yika:
Gb’ emi mi dide, Oluwa,
Ki nri O, ki nsi gbe O ga.
(Visited 495 times, 1 visits today)