1. KRIST, ologo, olola,
Iwo Imole aiye,
Orun ododo, dide,
K’ O si bori okunkun;
‘Mole oro sunmo mi,
‘rawo oro, w’aiya mi.
2. Okunkun l’owuro je
B’ Iwo ko pelu re wa;
Ailayo l’ ojo yi je,
B’anu ko tan ‘mole mi,
Fun mi n’ imole, Jesu;
M’okan mi gbogbo gbona.
3. Wa be okan mi mi yi wo,
Le okunkun ese lo;
F’ imole orun kun mi,
Si tu aigbagbo mi ka,
Ma f’ ara Re han si mi,
Si ma ran b’ osangangan.
(Visited 1,002 times, 1 visits today)