YBH 53

OTUN ife l’ o nfarahan

1. OTUN ife l’ o nfarahan,
Bi a ti nji l’ ojojumo,
Lat’ inu orun at’ okun,
A ji s’ agbara at’ ero.

2. Otun anu l’ ojojumo
L’o nra yi wa ka n’ okun,
Otun ‘dariji at’ abo,
Ero titun si nkan t’ orun.

3. Ife si ore a d’otun,
‘Gba ewa orun ba wo won,
Adura at’ ife y’o ro
Wahala at’ ise gbogbo.

4. Oluwa ninu ife Re,
Mu wa ye fun ‘simi orun;
K’O pa wa mo l’ ojo gbogbo,
K’ a le rin bi adura wa.

(Visited 348 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you