YBH 515

NIGBAT’ ipe ba dun

1. NIGBAT’ ipe ba dun,
Ngo dide n’nu ‘boji,
Ngo r’ Onidajo Alade,
Ri sanma t’ o ngbina.

2. Pel’ ayo tab’ ekun,
Ni ngo f’ iboji ‘le,
Kini yio pade mi l’ ona,
‘Bukun tabi egun?

3. N’nu ki mba Jesu gbe,
Tabi k a ta mi nu,
N’nu ki mb’ ase Re lo s’ orun,
Tabi ki nya s’ egbe.

4. Iwo ti ko fe ‘ku
Elese kansoso,
‘Wo t’ O ku lati gba mi la
Lowo ‘ya ailopin.

5. Ko mi bi a ti ye
Ona ‘binu sile,
Ki mba le fi ayo yo ‘ju
Nigb’ O ba d’ ori-‘te.

(Visited 292 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you