YBH 517

GBA ‘Wo Onidajo ba de

1. GBA ‘Wo Onidajo ba de
Lati m’ awon Tire lo ‘le,
Ngo ha wa l’ arin won?
Ao ha r’ ekolo lasan yi,
Ti eru iku ko ye ba
Li owo otun Re?

2. Mo fe ban won pejo nihin,
Lati ma wole l’ ese Re,
Bi mo tile s’ aiye;
Ara mi ha le gba b’ a ba
Fi oruko t’ emi s’ ehin,
N’ igba t’ O ba npe won?

3. K’ anu Re ma jek’ o ri be,
Oluwa, se ‘bi ‘sabi mi,
L’ ojo t’ o tobi yi;
Jeki ngb’ ohun ‘dariji Re,
Lati le aigbagbo mi lo,
Ma si jeki nsubu.

4. Jeki nwa l’ arin enia Re,
Gbat’ ipe Angeli ba dun,
Lati ri oju Re;
Em’ o korin l’ ohun goro,
‘Gba ‘bugbe Re l’ oke ban ho
Pel’ orin igbala.

(Visited 272 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you