YBH 518

KO s’ aye ‘jafara nihin

1. KO s’ aye ‘jafara nihin
Fun ‘reti at’ eru aiye;
B’ emi ki ba pe bo,
B’ o ba je pe b’ Onidajo
Ba yo, eda yio duro
Niwaju ‘te ‘dajo.

2. Ko s’ ohun ti mbar o nihin,
Lehin bi ngo ti se sala,
L’ owo ‘ku ailopin;
Bi ngo ti se rin b’ ayanfe,
Bi mo ba ku, bi ngo se le
N’ ile l’ oke orun.

3. Jesu, f’ oju anu wo mi,
Se Oluto at’ Ona mi,
Si ayo t’ o l’ ogo;
Ko ‘dariji si aiya mi,
Nigba ngo ba si lo nihin,
Ki nlo l’ alafia.

(Visited 338 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you