1. JESU Oluwa mbo,
Lati se ‘dajo wa,
Yio san f’ olukuluku,
Gege bi ise re.
2. Ebun t’ o fifun wa,
Lati fi s’ ise fun,
Yio pew a lati j’ iyin,
Gege b’ a ti lo won.
3. Jek’ a mura lati
Fi ebun wa sise,
Nigbat’ Olugbala ba de
K’ O le sure fun wa.
4. A fere gb’ ohun Re
Li awosanma na,
Yio ke tantan pe, “Emi de,”
Lati dajo aiye.
5. Yio si wi fun w ape
Wa alabukunfun,
Gba ‘joba t’ a pese fun nyin
Lati aiyeraiye.
(Visited 1,003 times, 1 visits today)