1. F’ AWON enia Re t’ o lo ‘smi
Awon ti o f’ igbagbo jewo Re,
Ki yin oruko Re, Olugbala,
Alleluya!
2. Iwo l’ apata won at’ odi won,
Iwo ni Balogun won l’ oju ‘ja
Iwo ni imole okunkun won,
Alleluya!
3. Jek’ awon omo-ogun Re l’ aiye,
Jagun nitoto b’ awon t’ igbani
Ki nwon le gba ade ogo bi won,
Alleluya!
4. Idapo ibukun wo l’ o to yi!
Awa nja nihin, awon nyo lohun;
Be Tire kanna l’ awa at’ awon.
Alleluya!
5. Gbat’ ija ba ngbona, ti ogun nle,
A dabi eni ngborin ayo won;
Igboiya a sid e, at’ agbra.
Alleluya!
6. Ojo nlo, orun wa fere won a,
Awon ajagun toto y’o simi;
Didun ni isimi Paradise,
Alleluya!
7. Lehin eyi ojo ayo kan mbo,
Awon mimo y’o dide n’nu ogo;
Oba ogo yio wa larin won,
Alleluya!
8. Lat’ opin ile, lat’ opin okun,
Ogunlogo nro wo ‘bode pearli
Nwon nyin Baba, Omo ati Emi.
Alleluya!
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.
Support the Hymn Archive