1. AKO n’ ibugbe kan nihin,
Eyi ba elese n’nu je;
Ko ye k’ enia mimo kanu,
‘Tori nwon nfe ‘simi t’ orun.
2. A ko n’ ibugbe kan nihin,
O buru b’ ihin je ‘le wa;
K’ iro yi mu inu wa dun,
Awa nwa ilu nla t’ o mbo.
3. A ko n’ ibugbe kan nihin,
A nwa ilu nla t’ a ko ri;
Sion ilu Oluwa wa,
O ntan imole titi lai.
4. Iwo ti se ‘bugbe ife,
Nibiti ero gbe nsimi;
Emi ba n’ iye b’ adaba,
Mba fo sinu re, mba simi.
5. Dake okan mi, ma binu,
Akoko Oluwa, l’ oye;
T’ emi ni se ‘fe Re,
Tire lati se mi l’ ogo.
(Visited 332 times, 1 visits today)