1. AWON mimo! Ija nwon pin,
Nwon segun aiye nikehin,
Nwon ko fe ohun ija mo;
Nwon da won si ese Jesu;
Awon mimo! Eni ‘bukun,
‘simi won mbe lese Jesu!
2. Awon mimo! irin won pin,
Nwon ko tun sure ije mo,
Are at’ isubu d’ opin,
Ota on eru ko si mo;
Awon mimo! eni ‘bukun,
‘Simi won dun n’ ile nla.
3. Awon mimo! ajo won pin,
Nwon gun s’ ebute ayo ni,
Nwon ko tun beru iji mo,
Tabi riru igbi okun;
Awon mimo! eni ‘bukun
L’ebute aabo ‘simi won.
4. Awon mimo! nwon nso ona,
‘Gbat’ ara won sun n’ iboji,
Tit’ igbala tin won y’o jinde
Lati ti ayo goke lo;
Enyin mimo! e ho f’ ayo;
Oluwa wa mbowa Kankan.
5. Olorun, Iwo l’ a nkepe,
Olugbala, ba wa bebe;
Emi Mimo, Oluto wa,
F’ ore-ofe fun wa d’opin;
K’ a le ba ‘won mimo simi
Ni Paradise pelu Re.
(Visited 991 times, 1 visits today)