1. TAL’ awon wonyi b’ iranwo,
Niwaju ‘te Olorun?
Gbogbo nwon de ade wura,
Egbe ogo wo l’ eyi?
Gbo! nwon nko, Alleluya,
Nwon nf’ iyin fun Oba won,
2. Tali awon ti nko mona,
T’ a wo l’ aso ododo;
Awon ti aso funfun won,
Y’o wa ni mimo titi,
Ti ki o si gbo lailai?
Nibo l’ egbe yi ti wa?
3. Awon wonyi l’ o ti jagun,
F’ ola Olugbala won,
Nwon ja titi d’ oju iku,
Nwon ko k’ egbe elese;
Awon ni ko sa f’ ogun,
Nwon segun nipa Kristi.
4. Awon yi l’ okan won gbogbe,
Ninu ‘danwo kikoro,
Awon l’ o ti fi adura
B’ Olorun jijakadi;
‘Rora ija won pari,
Olorun re won l’ ekun
5. Awon wonyi l’ o ti sona,
Nwon f’ ife won fun Kristi,
Nwon si ya ‘ra won si mmo,
Lati sin nigbagbogbo;
Nisisiyi li orun,
Nwon wa l’ ayo l’ odo Re.
(Visited 1,777 times, 1 visits today)