1. EGBEGBERUN aimoye
Nwon wo aso ala,
Ogun awon t’a rapada
Nwon kun ‘bi ‘mole naa;
Ija won pelu ese
At’ iku ti pari;
E si ‘lekun wura sile,
Fun awon asegun.
2. Iro Halleluyah won
Lo gb’aiye, orun kan;
Iro egbegberun Harpu
Ndun pe ‘segun de tan,
Ojo t’a seda aiye
T’ a da orile ‘de;
Ayo na pa ‘banuje re
Ti a fun ni kikun;
3. A! Ayo t’a ko le so
Leti bebe Kenaan,
Idapo nla wo lo to yi
N’ ibit’ a ki pinya;
Oju t’o kun f’ ekun ri
Yio tan ‘mole ayo;
Ki yio si alaini Baba,
Opo ki yio si mo.
4. Mu ‘gbala nla Re fun wa,
Od’ agutan t’a pa;
K’ oruko awon ayanfe;
Wa, ife oril’ede,
Wa da onde sile;
Wa fi ami ‘leri Re han;
Wa, Olugbala wa.
Amin.
(Visited 918 times, 1 visits today)