1. OPO ikan omi,
Yanrin kekeke;
Wonyi l’ o d’ okun nla
At’ ile aiye.
2. Iseju wa kokan,
Ti a ko kasi,
L’ o nd’ odun aimoye
Ti ainipekun.
3. Iwa ore die,
Oro ‘fe die,
L’ o ns’ aiye di Eden,
Bi oke orun.
4. Isise kekeke
L’ o nmokan sina,
Kuro l’ ona rere,
Si ipa ese.
5. Ise anu die
T’ a se l’ omode,
Di ‘bukun f’ omode,
T’ o jina rere.
6. Awon ewe l’ ogo
Ngberin Angeli;
Se wa ye Oluwa
F’ egbe mimo won.
(Visited 349 times, 1 visits today)