1. OJ’ oni lo
Jesu Baba,
Boju Re w’ emi omo Re.
2. ‘Wo Imole,
Se ‘toju mi;
Tan imole Re yi mi ka.
3. Olugbala,
Nko ni beru,
Nitori o Wa lodo mi.
4. Nigba gbogbo,
Ni oju Re,
Nso mi gbat’ enikan ko si.
5. Nigba gbogbo
Ni eti Re
Nsi si adura omode.
6. Nitori na
Laisi foya
Mo sun, mo si simi le O.
7. Baba Omo,
Emi Mimo
Ni iyin l’ orun l’ aiye.
(Visited 540 times, 1 visits today)