1. JESU Onirele,
Omo Olorun:
Alanu, Olufe,
Gbo ‘gbe omode.
2. Fi ese wa jin wa
Si da wa n’ ide;
Fo gbogbo orisa,
Ti mbe l’ okan wa.
3. Fun wa ni omnira,
F’ ife s’ okan wa;
Fa wa Jesu mimo,
S’ ibugbe l’ oke.
4. To wa l’ ona ajo,
Si je ona wa;
Ja okunkun aiye,
S’ imole orun.
5. Jesu Onirele
Omo Olorun,
Alanu, olufe,
Gbo gbe omo re.
(Visited 1,504 times, 3 visits today)