1. GB’ adura wa Oluwa,
F’ awon omo t’ O fun wa,
Pin wa ninu ‘bukun Re,
Si fun won l’ ayo l’ orun.
2. Je k’ okan won sunmo O,
Nigba won wa l’ omode,
Je ki nwon f’ ogo Re han,
L’ akoko ‘gba ewe won.
3. Fi eje Olugbala,
We okan wo mo toto;
Je k’ a tun gbogbo won bi,
Ki nwon si le je Tire.
4. Anu yi l’ a mbebe fun,
K’ O si gbo adura wa;
Iwo l’ a gb’ okan wa le,
Ni anu gb’ adura wa.
(Visited 1,633 times, 1 visits today)