1. OLORUN Bethel, Eniti
O mbo awon Tire;
Enit’ o mu baba wa la
Ojo aiye won ja.
2. A mu eje at’ ebe wa
Wa ‘waju ite Re,
Olorun awon baba wa,
Ma je Olorun wa.
3. Ninu idamu aiye yi,
Ma toju ipa wa,
Fun wa ni onje ojo wa,
At’ aso t’ o ye wa.
4. Na ojiji ‘ye Re bow a,
Tit’ ajo wa o pin,
Ati ni bugbe Baba wa,
Okan wa o simi.
5. Iru ibukun bi eyi,
L’ a mbere lowo Re;
Iwo o je Olorun wa,
At’ ipin wa lailai.
(Visited 4,758 times, 2 visits today)