1. MA so fun mi l’ ohun aro
Pe iye dabi ala;
Okan ti ntogbe li o ku,
‘Kan ko ri bi a ti nro.
2. Iye mbe se! Iye mbe se!
‘Boji ki si s’ opin re;
Ki se f’ okan l’ a so fun pe
Erupe pada se ‘pe.
3. Ki ‘s’ ayo tabi ‘banuje
Ni ala t’ a pa fun wa
Sugbon pe k’ ise ‘jojumo,
Lo siwaju ju t’ ana.
4. Ona gun, akoko nkoja,
Okan wa b’ o ti le ni,
Bi ewiri alagbede
‘Lu ilu isa-oku.
5. La ‘ju ‘ja aiye t’ o teju
Ni budo ogun aiye,
Ma je k’ a ma da o b’ eran;
Se akoni n’ ija na.
6. Ma gbekele ola b’ o dun!
Je k’ ana sin ‘ku ana,
Sise sise nsisiyi!
Li aiya se t’ Olorun.
7. Okiki awon eni nla
So pe awa le to, won;
Bi a ba si kuro l’ aiye
A le f’ ami wa sile.
(Visited 150 times, 1 visits today)