1. YIKA or’ ite Olorun,
Egberun ewe wa;
Ewe t’ a dari ese ji,
Awon egbe mimo,
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
2. Wo! Olukuluku won wo
Aso ala mimo
Ninu imole ailopin
At’ ayo ti ki sa,
Nkorin, etc.
3. Kil’ o mu won de aiye na,
Orun t’o se mimo,
Nib’ alafia at’ ayo,
Bi nwon ti se de be?
Nkorin, etc.
4. ‘Tori won, Jesu ta ‘je Re,
Lati k’ ese won lo;
A ri won ninu eje na,
Nwon di mimo laulau;
Nkorin, etc.
5. L’aiye, nwon wa Olugbala,
Nwon fe oruko Re;
Nisisiyi nwon r’ oju Re,
Nwon wa niwaju Re;
Nkorin, etc.
6. Orisun na ha nsan loni?
Jesu, mu wa de ‘be;
K’ a le ri awon mimo na,
K’ a si ba won yin O,
Nkorin, etc.
(Visited 376 times, 1 visits today)