YBH 555

ORE kan mbe fun omode

1. ORE kan mbe fun omode
Ninu awon orun;
Ore ti ki yipada,
T’ ife Re ko le ku;
Ko dabi ore aiye
Ti mbaje lododun;
Eni yiye l’ ore yi
Oruko Re owon.

2. Isimi kan mbe f’ omode
Ninu awon orun;
F’ awon t’ o f’ Olugbala,
Ti nke “Abba Baba;”
Isimi lowo ‘yonu,
Low’ ese at’ ewu;
Nibe l’ awon omode
Y’o simi titi lai.

3. Ile kan mbe fun omode
Ninu awon orun;
Nibiti Jesu njoba,
Ile alafia!
Ko s’ ile t’ o jo l’ aiye
T’ a le fi sakawe;
Ara r’ olukuluku;
Irora na d’ opin.

4. Ade kan mbe fun omode
Ninu awon orun;
Enit’ o ba now Jesu
Y’o ri ade na de;
Ade t’ o l’ ogo julo,
Ti y’o fi fun gbogbo
Awon ore re l’ aiye;
Awon t’ o fe nihin.

(Visited 437 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you