1. NIGBAKAN ni Betlehemu
Ile kekere kan wa;
Nib’ iya kan te ‘mo re si
Lori ibuje eran;
Maria n’ iya Omo na,
Jesu Kristi l’ Omo na.
2. O t’ orun was ode aiye,
On l’ Olorun Oluwa;
O f’ ile eran se ile,
‘Buje eran fun ‘busun,
Lodo awon otosi,
Ni Jesu gbe li aiye.
3. Ni gbogbo igba ewe Re
O ngoran, O si nteriba
Fun iya ti ntoju Re,
O nferan O si nteriba
O ye ki gbogb’ omode
K’ o se olugboran be.
4. ‘Tori On je awose wa,
A ma dagba bi awa,
O kere, ko le da nkan se,
A ma sokun bi awa,
O si le ba wa daro,
O le ba way o pelu.
5. Awa o si f’ oju wa ri
Ni agbara ife Re,
Nitori Omo rere yi
Ni Oluwa wa l’ orun,
Y’o to awa omo Re
S’ ona ibiti On lo.
6. Kise ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L’ awa o ri, sugbon l’ orun
Lowo otun Olorun,
B’ iranwo l’ awon ‘mo Re
Y’o wa n’nu aso ala.