1. NIHIN l’ Olorun sin mi de,
De ‘hin n’ ipa Re sun ‘jo mi,
Gbogbo asale yio si fi
Ami ore Re titun han.
2. Opo igba mi l’ o sofo,
Be boya mo sunmo ‘le mi;
Sugbon O dari t’ ehin ji,
O fun mi n’ ipa mi ‘waju.
3. Mo f’ara le ‘le lati sun,
Alafia n’ irori mi,
Awon angeli t’ a ti yan,
Si duro yi ori mi ka.
4. Gba oru iku yio ba de,
Ara mi yio sun ninu ‘le,
N’ ireti ohun ‘gbala Re,
Lati tu iboji mi ka.
(Visited 381 times, 1 visits today)