1. MOKANDILOGORUN dubule je,
Labe oji nin’ agbo;
Sugbon okan je lo s’ or’ oke,
Jina s’ ilekun wura;
Jina rere lor’ oke sisa,
Jina rere s’ Olus’ agutan.
2. “Mokandilogorun Tire l’ eyi;
Jesu, nwon ko ha fun O?”
Olus’ agutan dahun, “T’ emi yi
Ti sako lodo Mi;
B’ ona tile ri palapala,
Ngo w’ aginju lo w’ agutan Mi.”
3. Okan nin’ awon t’ a ra pada
Ko mo jijin omi na,
Ati dudu oru ti Jesu koja
K’ O to r’ agutan Re he,
L’ aginju rere l’ O gbo ‘gbe re,-
O ti re tan, o si ti ku tan
4. “Nibo n’ iro eje ni ti wa,
T’ o f’ ona or’ oke han?”
“A ta sile f’ enikan t’ o sako
K’ Olusagutan to mu pada,”
“Jesu, kil’ oya owo Re be?”
“Egun pupo l’ o gun Mi nibe.”
5. Sugbon ni gbogbo ori oke
Ati lori apata,
Igbe ta d’ oke orun wipe,
“Yo, Mor’ agutan Mi he!”
Y’ ite ka l’ awon Angel’ ngba
“Yo! Jesu m’ ohun Tire pada!”