YBH 592

MO fe gbo itan kanna

1. MO fe gbo itan kanna
T’ awon Angeli-nso;
Bi Oba Ogo ti wa,
Gbe aiye osi yi;
Bi mo tile j’ elese,
Mo mo eyi daju,
Pe Oluwa wa gba mi,
‘Tori On feran mi.

2. Mo yo pe Olugbala,
Ti je omode ri;
Lati fi ona mimo,
Han awon omo Re;
Bi emi ba si tele
Ipase Re nihin,
On ko ni gbagbe mi lai
‘Tori On feran mi.

3. Ife ati anu Re,
Y’o je orin fun mi;
B’ emi ko tile le ri,
Mo mo pe O ngbo mi
O si ti se ileri,
Pe mo le lo Korin
Larin awon Angeli
‘Tori On feran mi.

(Visited 432 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you