YBH 593

WA, enyin olope, wa

1. WA, enyin olope, wa,
Gbe orin ikore ga;
Ire gbogbo ti wole
K’ otutu oye to de;
Olorun Eleda wa
L’ O ti pese f’ aini wa;
Wa k’a re ‘le Olorun
Gbe orin ikore ga.

2. Oko Olorun l’ aiye,
Lati s’ eso iyin Re;
Alikama at’ epo
Ndagba f’ aro tab’ ayo;
Ehu na, ipe tele,
Siri oka nikehin;
Oluwa ‘kore, mu wa
Je eso rere fun O.

3. N’tori Olorun w ambo,
Y’o si kore Re sile;
On o gbon gbogbo panti
Kuro l’ oko Re n’jo na;
Y’o f’ ase f’ awon Angel’
Lati gba epo s’ ina,
Lati ko alikama
Si aba Re titi lai.

4. Beni, ma wa, Oluwa
Si ikore ikehin;
Ko awon enia Re jo
Kuro l’ ese at’ aro;
So won di mimo lailai
Ki nwon le ma ba O gbe;
Wa t’ Iwo t’ Angeli Re,
Gbe orin ikore ga.

(Visited 3,268 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you