YBH 594

OHUN ogo Re l’ a nrohin

1. OHUN ogo Re l’ a nrohin,
Sion’ ti Olorun wa;
Oro Enit’ a ko le ye,
Se o ye fun ‘bugbe Re,
L’ ori apat’ aiyeraiye,
Kini le mi ‘simi re?
A f’ odi gbala yi o ka,
K’ o le ma rin ota re.

2. Wo! Ipa omi alaigbe,
Nt’ ife Olorun sun wa,
O to-fun gbogbo omo Re,
Eru aini ko si mo;
Tal’ o le re, ‘gba odo na
Ba nsan t’ o le p’ ongbe re?
Or’-ofe Olodumare
Ki ye lat’ irandiran.

3. Ara Sion alabukun,
T’ a f’ eje Oluwa we;
Jesu na ti nwon ngbekele,
So won d’ oba, woli Re,
Sisa l’ ohun afe aiye
Gbogbo eye oro re,
Isura toto at’ ayo
Kik’ omo Sion’ l’ o mo.

(Visited 390 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you