1. YO, eyin onigbagbo,
Je k’ imole nyin tan;
Igba ale mbo tete,
Oru si fere de.
Oko iyawo dide,
O fere sunmo ‘le;
Dide, gbadura, sora,
L’ oru n’ igbe y’o ta.
2. E be fitila nyin wo,
F’ ororo sinu won;
E duro de ‘gbala nyin
Ipari ‘se aiye;
Awon oluso nwipe,
Oko ‘yawo de tan;
E pade re, b’ o ti mbo,
Pelu orin iyin.
3. Enyin iyawo mimo,
Gbe ohun nyin soke
Titi, n’nu orin ayo
Pelu awon Angel’
Onje iyawo se tan,
‘Lekun na si sile,
Dide, arole ogo
Oko iyawo mbo.
4. Enyin ti e nfi suru
Ru agbelebu nyin,
E o si joba lailai
‘Gbati ‘ponju ba tan,
Yi ite ogo Re ka
E o r’ Od’ agutan,
E o f’ ade ogo nyin
Lele niwaju Re.
5. Jesu, ‘Wo ireti wa
F’ ara Re han fun wa,
Wo Orun t’ a ti nreti
Ran s’ ori ile wa;
A gbe owo wa s’ oke,
Oluwa je k’ a ri
Ojo ‘rapada aiye
T’ o mu wa d’ odo Re.