YBH 598

JESU, aso ododo Re

1. JESU, aso ododo Re
L’ ewa at’ ewu ogo mi,
L’ aiye etan bi mba gbe wo,
L’ ayo ni ngo gb’ ori s’ oke.

2. ‘Gba mba dide n’nu ara ‘ku,
Lati gba ‘bugbe mi l’ oke,
Eyi ni y’o j’ aroye mi;
“Jesu wa, O si ku fun mi.”

3. Mimo li aso na titi,
‘Gba ara mi ba di ogbo;
Ogbo ko le p’ ewa re da,
Titun l’ aso Kristi titi.

4. Jeki oku ko gb’ ohun Re,
Ki awon ti a tanu yo;
Ewa, at’ aso ogo won
L’ Olugbala, Ododo wa.

(Visited 545 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you