YBH 599

WA ba mi gbe! ale fere le tan

1. WA ba mi gbe! ale fere le tan,
Okunkun nsu; Oluwa ba mi gbe,
Bi oluranlowo miran ba ye,
Iranwo alaini, wa ba mi gbe.

2. Ojo aiye mi nsare lo s’ opin,
Ayo aiye nku, ogo re nwo ‘mi;
Ayida at’ ibaje ni mo nri;
‘Wo ti ki yipada, wa, ba mi gbe.

3. Mo nfe O ri ni wakati gbogbo;
Ki l’ o le segun esu b’ ore Re?
Tal’ o le se amona mi bi Re?
N’nu ‘banuje at’ ayo, ba mi gbe.

4. Pelu ‘Bukun Re, eru ko ba mi;
Ibi ko wuro, ekun ko koro;
Oro iku da? segun isa da?
Ngo segun sibe, b’ Iwo ba mi gbe.

5. Ki nr’oro Re ni wakati iku,
Se ‘mole mi, si toka si orun;
B’ aiye ti koja, k’ ile orun
Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe.

(Visited 8,224 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you