1. BABA orun! Emi fe wa
N’ iwa mimo, l’ ododo;
Sugbon ife eran’-ara
Ntan mi je nigbagbogbo.
2. Alailera l’ emi se,
Emi mi at’ ara mi;
Ese ‘gbagbogbo ti mo nda
Wo mi l’ orun b’ eru nla.
3. Ofin kan mbe li okan mi,
‘Wo papa l’ O fi sibe;
‘Tori eyi ni mo fi fe
Tele ‘fe at’ ase Re.
4. Sibe bi mo fe se rere,
Lojukanna mo sina;
Rere l’ oro Re ima so;
Buburu l’ emi sin se.
5. Nigba pupo ni mo njowo
Ara mi fun idanwo;
Bi a tile nkilo fun mi
Lati gafara f’ ese.
6. Baba orun, Iwo nikan
L’ O to lati gba mi la;
Olugbala ti O ti ran
On na ni ngo gbamora.
7. Fi Emi Mimo Re to mi
S’ ona titun ti mba gba;
Ko mi, so mi, k’ O si to mi
Iwo Emi Olorun.
(Visited 454 times, 1 visits today)