1. OKAN mi, odun kan ninu
Aiye re koja lo;
Eni ko le gbe ihin pe,
Eyi le j’ opin mi.
2. Ji okan mi, f’ opo suru
Be iduro re wo;
Kini ohun t’ o gbekele?
Kini ireti re?
3. Wo! odun miran tun bere;
Tun mura ajo re,
Wa anu fun ese t’ o da,
L’ ofe ninu Kristi.
4. Fi ara re fun Olorun,
Gbekele or-ofe Re,
F’ itara to ona orun,
‘Kehin re yio l’ ayo.
(Visited 292 times, 1 visits today)