1. LASAN ni ero mi nwa ‘pa,
T’ o ye fun okan mi kiri;
Okan mi ko le n’ isimi,
Tor’ aiye ko le bukun mi.
2. A ha le ri ayo pipe
Nibiti igba nyipada,
T’ akoko nfi iyara gba,
Afe aiye lo loju wa?
3. Dide, ‘wo okan mi, dide,
F’ aiye sile fo lo s’ oke,
Nibe l’ ayo gbe wa titi,
Gba akoko ba koja tan.
4. Oluwa fun mi l’ or-ofe
Ore Re le gb’ okan mi ga,
De ‘b’ ayo pipe t’ o l’ ogo,
T’ akoko ko le da duro.
(Visited 261 times, 1 visits today)